ÒNÍ WÁKÀTÍ MERINLELOGUN LÁTI TỌRỌ AFORIJIN BI O ṢE PÉ SUNDAY IGBOHO NI Ọ̀DARÀN TÀBÍ…..

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 3, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ọga àgbà Ọlọpa IG Tunde Disu ṣe ìfilọ́lẹ̀ Aapu Vigilant tí yóò mu ìwà ọ̀daràn dínkù lawujo….

Ariwo tí tún gbà ọ̀nà ọtun yọ bí loya Us-Imam (Usman), aṣoju òfin fún Ilorin Heritage Preservation Foundation, sọ ninu ẹjọ ti o n lọ lọwọ nipa Abdulazeez Adegbola (Tani Ọlọhun) ati Sunday Igboho.

 

Gẹgẹ bi iroyin Hallmark News, loya naa pe Tani Ọlọhun ati Igboho ni “criminals” (awọn ọdaran) ninu ọrọ rẹ ni ile-ẹjọ lẹhin igbiyanju lati mu Tani Ọlọhun ni Ibadan ni August 25. O sọ pe:

“A sọ fún ilé ẹjọ́ láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn torí Odaran tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ (Tani Ọlọ́run) láti mú bí ó ṣe tàpá sì àṣẹ ilé ẹjọ́, lọ́nà kejì àwọn ọ̀daràn ẹgbẹ́ ẹ bí Sunday Igboho”

Ọrọ yii lo fa ki agbẹnusọ Sunday Igboho dahun ni fidio ti o gbòòrò lori Facebook, ti o beere:

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Orile-ede Amerika tí sọpe kosi ẹsun ọ̀daràn kánkán tí Ààrẹ Tinubu ni pẹlu ilẹ̀ wá Lẹ́tà FBI fi hàn kedere…

“Ile-ẹjọ wo lo ti fi idi rẹ mulẹ pe Igboho jẹ ọdaran?”

Agbẹnusọ naa fun Us-Imam ni wakati 24 lati yọ ọrọ naa kuro, ti kii ba ṣe bẹ, wọn yoo tẹle ọna ofin.

Sunday Igboho lásìkò to n de sì ibi tí àwọn Ọlọpa tí fẹ́ mú Tani Ọlọ́run nilu Ìbàdàn

Kini ẹjọ gidi naa?

Ilorin Heritage Preservation Foundation pe Tani Ọlọhun lọ sile-ẹjọ nitori fidio kan ti wọn sọ pe o fi ẹsẹ mọ adura Islam. Warrant mu ni Upper Area Court, Ilorin gbe jade lati mu u. Nigba ti ọlọpa Kwara lọ si Ibadan lati mu u ni August 25, awọn olugbe Ayegun Oleyo ati Sunday Igboho da wọn duro, wọn si tu Tani Ọlọhun silẹ. Foundation naa n pe fun iwadii IGP lori idiwọ naa.

 

Ibeere Ofin Pataki:

Ṣe o yẹ ki eniyan pe ẹlomiran ni “ọdaran” ni gbangba lai si idajọ ile-ẹjọ? Ofin Naijiria sọ pe eniyan ni a ka si alaiṣẹ titi ile-ẹjọ fi sọ pe o jẹbi. Ọrọ Us-Imam nibi jẹ ẹgan tabi abuku ti o le fa ẹjọ.

 

Iwadi OJB News Yoruba: Titi di isisiyi, ko si ile-ẹjọ kankan ni Naijiria ti o ti da Sunday Igboho lẹjọ bi ọdaran. Awọn ẹjọ ti o ni ni Benin Republic ti pari pẹlu ominira rẹ.

 

ṢE YOO TỌRỌ AFORIJIN, ABI YOO DURO LORI Ọ̀RỌ̀ RẸ?

Gbogbo oju wa lori Us-Imam bayi.

Kini ero yin? Ṣe o tọ ki a pe eniyan ni ọdaran laisi idajọ ile-ẹjọ? Sọ ninu comment!

 

#OJBNewsYoruba #SundayIgboho #TaniOlohun #UsImam #IroyinPajawiri #YorubaNation #Ilorin #Ibadan #Ofin

2 thoughts on “ÒNÍ WÁKÀTÍ MERINLELOGUN LÁTI TỌRỌ AFORIJIN BI O ṢE PÉ SUNDAY IGBOHO NI Ọ̀DARÀN TÀBÍ…..”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.