Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 6, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Aare Bola Ahmed Tinubu ti yan Ayodele Fayose, Gomina tẹlẹri ipinlẹ Ekiti, gẹgẹ bi Alaga Igbimọ Abala Ina Abule (Rural Electrification Agency – REA).
ÈRÒJÀ PÀTÀKÌ:
• Ọjọ yiyan: July 20-21, 2026 ni Abuja, gẹgẹ bi atẹjade lati ọdọ Bayo Onanuga, Agbẹnusọ Aare.
• Iye awọn ti a yan: Awọn eniyan 26 ni a yan sinu igbimọ awọn ile-iṣẹ ijọba apapọ 10. Fayose ni ọkan ninu wọn.
• Ipa REA: Ile-iṣẹ REA ni o n ri daju pe awọn abule ati igberiko ni Naijiria ni imọlẹ ina.
• Awọn ẹlẹgbẹ rẹ: Alhaji Ahmadu Abubakar ati Engineer Ilyasu Ibrahim Makinta ni members, pẹlu DG ti o wa tẹlẹ, Abba Abubakar Aliyu.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
ARÍYÀNJIYÀN TÓ WÀ?
Iyanu ni pe oṣu diẹ sẹhin, Fayose ti sọ pe oun yoo jẹ ki o duro si ile ju ki o gba ipo labẹ ijọba APC lọ. Arakunrin rẹ, Isaac Fayose, paapaa sọ lori Facebook pe “My brother won’t accept yeye appointment” ati pe ki o fi ipo naa fun awọn ọmọ rẹ.
Ṣugbọn ni bayi, Fayose ti gba ipo naa, o si ti ṣetan lati bẹrẹ iṣẹ. Awọn kan sọ pe o jẹ ere oselu, awọn kan sọ pe o jẹ anfani lati sin ilu.
KINI REA N ṢE?
REA ni ile-iṣẹ ti o n mu ina lọ si awọn abule ti NEPA ko tii de. Ti Fayose ba ṣiṣẹ daradara, awọn abule ni Ekiti ati gbogbo Naijiria yoo ni imọlẹ.
