ỌPẸ Ó! WỌN TÍ GBA ÀWỌN TÁWỌN BANDIITI JI KO NI ÌPÍNLẸ̀ KWARA PADÀ

*Ìjọba Kwara dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ Ààrẹ Bọ́lá Tinubu àtàwọn agbófinró tó ṣiṣẹ́ takuntakun

 

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Busari Nurudeen, Kwara | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú 5, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Ilé ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara ti kéde ayọ̀ ńlá lónìí pé àwọn èèyàn mejidinlogoji (38) tí àwọn adigunjale ji gbé ní abúlé Woro àti Nuku, ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama, ní oṣù kejì ọdún 2026 yìí, ti gba ìtúsilẹ̀ kúrò nínú igbó.

 

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí OJB News Yorùbá, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé ní alẹ́ ọjọ́ kẹta oṣù kejì, ọdún 2026, nígbà tí àwọn banditi apani yọ́ wọ Woro àti Nuku. Ìjọba Kwara àti àwọn olórí àdúgbò sọ pé ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn ló kú, tí wọ́n sì ji àwọn obìnrin, àwọn abiyamọ àti àwọn ọmọdé lọ.

 

Alukoro Gómìnà Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, Rafiu Ajakaye, ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé:

“Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ iṣẹ́ líle láti ọwọ́ àwọn agbófinró àti àwọn aṣojú ìjọba, a ní inú dídùn láti kéde òmìnira àwọn èèyàn 38 náà”.

Ààrẹ Bọ́lá Tinubu fúnra rẹ̀ tún jẹ́rìí sí ìtúsilẹ̀ náà, ó sì sọ pé òun ti ń tẹ̀lé ìṣẹ̀lẹ̀ ààbò ní orílẹ̀-èdè náà pẹlẹpẹlẹ.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

*O tan o, wọn ti wọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord àti INEC lọ sile ẹjọ́ nítorí Oriyomi Hamzat https://ojbmediashub.com.ng/blog/busari-gudugudu-wo-egbe-accord-ati-inec-rele-ejo-nitori-oriyomi-hamzat/

*Peller ni ọpọlọpọ owo dollar tí wọn náà fún òun níbi ìgbéyàwó òun, ayédèrú ni https://ojbmediashub.com.ng/blog/peller-figbe-ta-leyin-ti-opo-owo-dola-ti-won-fi-mo-lori-lojo-igbeyawo-re-je-ayederu/

 

Ìjọba Kwara sọ pé aṣeyọrí yìí wá látàrí ìgbésẹ̀ taara ti Ààrẹ Tinubu tí ó ṣamọ̀nà ipa láti gba àwọn olùfaragba náà sílẹ̀.

Àwọn ará Woro àti Nuku bẹ̀rẹ̀ sí ní ayẹyẹ ayọ̀, wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn èèyàn wọn ti padà sílé láìléwu. Ìjọba sì ṣèlérí pé wọn yóò tẹ̀síwájú láti wá àwọn míràn tí ó ṣẹ́kù kí àlàáfíà tó péye lè padà sí Kaiama.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.