BUSARI GUDUGUDU WỌ ẸGBẸ́ ACCORD ÀTI INEC RE’LE ẸJỌ NÍTORÍ ORIYOMI HAMZAT

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú 5, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Ẹjọ nla ti bẹrẹ ni ilé ẹjọ́ giga lẹhin ti Olakunle Busari ti gbogbo eniyan mọ si Gudugudu fi ẹ̀sùn kan ẹgbẹ Accord Party ati INEC.

 

KÍNNÍ O ṢẸLẸ̀? 

Gẹgẹ bi iwadi OJB News Yoruba:

Ìwádìí wá fihàn pé ìkùnsínú tí wá lákòókò tí wọn ń ṣètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú Accord ni ipinlẹ Ọyọ, eyii ni àbọ̀ ìwádìí wá, kí a mú wá fún yín ní ipele ń pele

1. Ibo Abẹnu Onigun Mẹta: Ni oṣu May 2026, ẹgbẹ Accord Party ni Oyo ṣe ibo abẹnu gomina. Awọn oludije mẹta ni Oriyomi Hamzat (gbajugbaja oniroyin Agidigbo FM), Olakunle Busari Gudugudu, ati Fatai Owoseni, AIG tẹlẹ.

 

2. Awọn Abajade Meji: Iha kan ti National Secretary Adebukola Ajaja ati INEC ṣe abojuto kede Busari Gudugudu gẹgẹ bi olubori pẹlu ibo 29,427, Oriyomi 18,716, Owoseni 11,922. Iha keji lori fidio X kede Oriyomi Hamzat gẹgẹ bi oludije gidi pe awọn meji yoku ni a yọ kuro nitori wọn ko pari iwe.

 

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ

Peller tí fi ariwo tá pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó dollar tí wọn náà fún òun níbi ìyàwó òun jẹ́ ayédèrú https://ojbmediashub.com.ng/blog/peller-figbe-ta-leyin-ti-opo-owo-dola-ti-won-fi-mo-lori-lojo-igbeyawo-re-je-ayederu/

 

3. Ẹjọ Busari: Busari Gudugudu ni Oriyomi Hamzat ko yẹ ki o kopa ninu ibo abẹnu naa rara nitori ko yege ninu screening, o si de lẹyin ti screening ti pari. Nitorina o wo ẹgbẹ ati INEC lọ si ile-ẹjọ lati di orukọ Oriyomi duro ki INEC ma gba.

 

4. Ipo National: Ẹgbẹ apakan ti Prof. Chris Imumolen dari ti sọ pe ko si ọkan ninu awọn mejeeji ni oludije gidi, o ti fagile gbogbo ibo abẹnu Oyo naa, o ni yoo tun ṣe ibo tuntun.

 

Bayi ọrọ naa wa niwaju ile-ẹjọ, INEC si ti beere fun akoko lati dahun. A n reti idajọ laipẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.